Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 16:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Òdiwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.

12. Àwọn ọba kórìírà ìwà àìtọ́nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.

13. Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣòótọ́ènìyàn tí ń sọ òtítọ́ ṣe iyebíye sí wọn.

14. Ìrànṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.

15. Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;ojú rere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

16. Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọàti láti yan òye dípò o fàdákà!

17. Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.

18. Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú,

19. ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrin àwọn olùpọ́njújù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.

20. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ire,ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.

21. Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóyeọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.

Ka pipe ipin Òwe 16