Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 15:18-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.

19. Ẹ̀gún dí ọ̀nà ọ̀lẹṣùgbọ́n pópónà tí ń dán ni ti àwọn dídúró ṣinṣin.

20. Ọlọgbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ kẹ́gàn baba rẹ̀.

21. Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀;ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.

22. Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn;ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràwà.

23. Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó báa muọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!

24. Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọgbọ́nláti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú.

25. Olúwa fa ilé onígbéraga ya lulẹ̀,Ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó mọ́ láìyẹ̀.

26. Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú,

27. Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.

28. Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wòṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.

29. Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.

30. Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn,ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.

31. Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè,yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.

32. Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀,Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ síi.

33. Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

Ka pipe ipin Òwe 15