Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 15:16-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wàju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.

17. Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wàsàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.

18. Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.

19. Ẹ̀gún dí ọ̀nà ọ̀lẹṣùgbọ́n pópónà tí ń dán ni ti àwọn dídúró ṣinṣin.

20. Ọlọgbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn,ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ kẹ́gàn baba rẹ̀.

21. Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀;ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.

22. Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn;ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràwà.

23. Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó báa muọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!

24. Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọgbọ́nláti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú.

25. Olúwa fa ilé onígbéraga ya lulẹ̀,Ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó mọ́ láìyẹ̀.

26. Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú,

27. Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.

28. Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wòṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.

29. Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.

30. Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn,ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.

31. Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè,yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.

32. Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀,Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ síi.

33. Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n,Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

Ka pipe ipin Òwe 15