Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 15:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padàṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.

2. Ahọ́n ọlọgbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jádeṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.

3. Ojú Olúwa wà níbi gbogbo,Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.

4. Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyèṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.

5. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọgbọ́n.

6. Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.

7. Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.

8. Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ẹ lọ́rùn.

9. Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.

10. Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an,ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.

11. Ikú àti ìparun sí sílẹ̀ níwájú Olúwamélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.

12. Ẹlẹ́gàn kórìíra ìbáwí:kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.

Ka pipe ipin Òwe 15