Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 13:10-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ niṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kó jọ yóò sí lọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀ díẹ̀ yóò pọ̀ síi.

12. Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

13. Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

14. Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹkùn ikú.

15. Òye pípé ń mú ni rí ojú rereṢùgbọ́n ọ̀nà aláìsòótọ́ kì í tọ́jọ́.

16. Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

17. Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdàámúṣùgbọ́n aṣojú olóòtọ́ mú ìwòsàn wá.

18. Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di talákà yóò sì rí ìtìjú,ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

19. Ìfẹ́ tí a múṣẹ dùnmọ́ ọkànṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.

20. Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́nṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

21. Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.

22. Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

23. Ilẹ̀ ẹ talákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko wáṣùgbọ́n àìsòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.

24. Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa báa wí.

Ka pipe ipin Òwe 13