Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Òwe 13:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ niṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

11. Owó tí a fi ọ̀nà èrú kó jọ yóò sí lọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀ díẹ̀ yóò pọ̀ síi.

12. Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.

13. Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.

14. Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹkùn ikú.

15. Òye pípé ń mú ni rí ojú rereṢùgbọ́n ọ̀nà aláìsòótọ́ kì í tọ́jọ́.

16. Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

Ka pipe ipin Òwe 13