Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 8:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, èmi pè yín ní ìjà,Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè,Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.

5. Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti ihà,tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde;níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.

6. Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdìbí èdìdì lé apá rẹ;nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,ìjowú sì le bí isà òkújíjò rẹ̀ rí bí ìjò iná,gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ iná Olúwa.

7. Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;Bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátapáta.

8. Àwa ní arábìnrin kékeré kan,òun kò sì ní ọmú,kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa,ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?

9. Bí òun bá jẹ́ ògiri,Àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí.Bí òun bá jẹ́ ilẹ̀kùn,Àwa yóò fi pákó kédárì dí i

10. Èmi jẹ́ ògiri,ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.

11. Sólómónì ní ọgbà àjàrà kan ní Báálí-Hómónìó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́júolúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wáẹgbẹ̀rún fàdákà.

12. Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi;ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Sólómónì,igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

13. Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà,àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ,Jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 8