Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 8:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin misí mi èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà!Èmi ìbá rí ọ ní òde,èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu,wọn kì bá fi mi ṣe ẹlẹ́yà.

2. Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyámi, ìwọ ìbá kọ́ mièmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòrùn dídùn fún ọ muàti oje èso pómégíránéètì mi.

3. Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi,ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbá mí mọ́ra.

4. Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, èmi pè yín ní ìjà,Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè,Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 8