Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 6:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,Ìwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin?Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,kí a lè bá ọ wá a?

2. Olùfẹ́ mi ti ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,sí ibi ibùsùn tùràrí,láti máa jẹ nínú ọgbàláti kó ìtànná lílì jọ.

3. Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,Ó ń jẹ láàárin ìtànná lílì,

4. Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tírísà,Ìwọ lẹ́wà bí i Jérúsálẹ́mù,ìwọ lẹ́rù bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.

5. Yí ojú rẹ kúrò lára mi;nítorí ojú rẹ borí mi.Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gílíádì.

6. Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,gbogbo wọn bí ìbejì,kò sì sí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.

7. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bá ìbòjú rẹ,rí bí ẹ̀là èso pómégíránéètì.

8. Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,àti ọgọ́rin àlè,àti àwọn wúndíá láìníye.

9. Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ,ààyò ẹyọkan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fúnÀwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fun-un

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 6