Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 2:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrínWò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri waÓ yọjú ní ojú fèrèséÓ ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà

10. Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,“Dìde, Olùfẹ́ mi,Arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.

11. Wò ó! Ìgbà otútù ti kọjá;Òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.

12. Àwọn òdòdó fara hàn lórí ilẹ̀Àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ déA sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.

13. Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jádeÀwọn àjàrà nípa ìtànná wọn fún ni ní òórùn dídùnDìde, wá, Olùfẹ́ mi;Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”

14. Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta,ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga,fi ojú rẹ hàn mí,jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ;Nítorí tí ohùn rẹ dùn,tí ojú rẹ sì ní ẹwà.

15. Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kékèkétí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtàná.

16. Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀;Ó ń jẹ láàrin àwọn lílì.

17. Títí ìgbà ìtura ọjọ́títí òjìji yóò fi fò lọ,yípadà, olùfẹ́ mi,kí o sì dàbí abo egbintàbí ọmọ àgbọ̀nrínlórí òkè Bétérì.

Ka pipe ipin Orin Sólómónì 2