Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 9:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé:Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburútàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùngẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibití ó ṣubú lù wọ́n láì rò tẹ́lẹ̀.

13. Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn:

14. Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yìí po, ó sì kọ́ ilé-ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì síi.

15. Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ ọlọgbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n-ọn rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin talákà náà.

16. Nítorí náà mo ṣọ wí pé “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin talákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.

Ka pipe ipin Oníwàásù 9