Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 7:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ọgbọ́n máa ń mú kí Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbáraju alákòóṣo mẹ́wàá lọ ní ìlú

20. Kò sí olódodo ènìyàn kan láyétí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.

21. Má ṣe kíyè sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.

22. Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹpé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmìíràn.

23. Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọgbọ́n”ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.

24. Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?

25. Mó wá ròó nínú ọkàn mi láti mọ̀,láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́nàti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ àgọ́ ìwàbúburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.

26. Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọobìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkútétí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.

27. Oníwàásù wí pé, “Wò ó” eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí:“Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.

28. Nígbà tí mo sì ń wá a kiriṣùgbọ́n tí n kò rí ìmo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrin ẹgbẹ̀rúnṣùgbọ́n n kò rí obìnrin,kankan kí ó dúró láàrin gbogbo wọn.

29. Eléyìí nìkan ni mo tíì rí:Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára,ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ.”

Ka pipe ipin Oníwàásù 7