Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 5:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.

10. Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùnpẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún-un.

11. Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ síináà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ síiÈrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí oní nǹkanbí kò se pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rírí wọn?

12. Oorun alágbàṣe a máa dùn,yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀kì í jẹ́ kí ó ṣùn rárá.

13. Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùnọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun oní nǹkan.

14. Tàbí ọrọ̀ tí ó ṣọnù nípa àìrí ojúrere,nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrinkò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún-un.

15. Ìhòòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúròkò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.

16. Ohun búburú gbáà ni eléyìí pàápàá:Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọkí wá ni èrè tí ó jẹnígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?

17. Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ọ rẹ̀,pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.

18. Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀ nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún-un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí.

Ka pipe ipin Oníwàásù 5