Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 5:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Tàbí ọrọ̀ tí ó ṣọnù nípa àìrí ojúrere,nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrinkò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún-un.

15. Ìhòòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúròkò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.

16. Ohun búburú gbáà ni eléyìí pàápàá:Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọkí wá ni èrè tí ó jẹnígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?

17. Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ọ rẹ̀,pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.

18. Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀ nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún-un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí.

19. Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún-un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ̀—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.

20. Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ́kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀.

Ka pipe ipin Oníwàásù 5