Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 4:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fàá sókè,ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubútí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn-án lọ́wọ́!

11. Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá ṣùn pọ̀, wọn yóò móoru.Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?

12. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn-ún yàra fà já

Ka pipe ipin Oníwàásù 4