Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 4:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo sì tún wò ó, mo sì ri gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn:mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kòsì ní Olùtùnú kankan,agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lárawọn kò sì ní olùtùnú kankan.

2. Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kútí wọ́n sì ti lọ,ó ṣàn fún wọn ju àwọntí wọ́n sì wà láàyè lọ.

3. Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn juàwọn méjèèjì lọ:ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburútí ó ń lọ ní abẹ́ oòrun.

4. Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbáratagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, aṣán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

5. Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kòó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.

6. Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́jẹ́jẹ́ pèlú wàhálà,àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.

7. Lẹ́ẹ̀kan síi mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:

8. Ọkùnrin kan dá wà,kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbíwàhálà rẹ̀ kò lópin,ṣíbẹ̀, ọ̀rọ̀ ohun ìní rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó bèèrè pé,“Nítorí ta ni mo ṣe ń ṣe wàhálà”“àti wí pé kí ni ìdí tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”Eléyìí náà aṣán niiṣẹ́ ìbànújẹ́ ni.

9. Ẹni méjì ṣàn ju ẹnìkan,nítorí wọ́n ní ààbò rere fún iṣẹ́ wọn:

10. Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fàá sókè,ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubútí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn-án lọ́wọ́!

Ka pipe ipin Oníwàásù 4