11. Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹ̀gún, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dàbí èso tí a kàn pọ̀ dáradára tí olùṣọ́-àgùntàn kan fi fún ni.
12. Àti síwájú láti inú èyí, Ọmọ-ọ̀n mi, gba ìmọ̀ràn.Nínú ìwé púpọ̀, òpin kò sí, ìwé kíkà púpọ̀ a máa mú ara ṣàárẹ̀.
13. Níṣinsìn yìí,òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé:Bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.
14. Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́àti ohun ìkọ̀kọ̀,kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.