Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 8:25-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀-tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun ṣíbẹ̀.

26. Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó bèèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn ún méje (1700) ìwọ̀n ṣékélì èyí tó kìlógírámù mọ́kàndínlógún ààbọ̀ (19.5 kilogram), láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ eléṣé àlùkò tí àwọn ọba Mídíánì ń wọ̀ tàbí àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tí ó wà ní ọrùn àwọn ràkúnmí wọn.

27. Gídíónì fi àwọn wúrà náà ṣe Éfódì èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Òfírà ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sọ ara wọn di aṣẹ́wó nípa sínsìn ní ibẹ̀. Ó sì di ẹ̀ṣẹ̀ fún Gídíónì àti ìdílé rẹ̀.

28. Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Mídíánì ba níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbérí mọ́. Ní ọjọ́ Gídíónì, Ísírẹ́lì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún.

29. Jerub-Báálì ọmọ Jóásìa padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀.

30. Àádọ́rin ọmọ ni ó bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó.

31. Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣékémù, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ábímélékì.

32. Gídíónì ọmọ Jóásì kú ní ògbólógbó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin-ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ófírà ti àwọn ará Ábíésérì.

33. Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gídíónì ni àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àgbérè tọ Báálì lẹ́yìn, wọ́n fi Báál-Beriti ṣe òrìṣà wọn.

34. Wọn kò sì rántí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn gbogbo tí ó wà ní gbogbo àyíká wọn.

35. Wọ́n kùnà láti fi inú rere hàn sí ìdílé Jérú-Báálì (èyí ni Gídíónì) fún gbogbo ore tí ó ṣe fún wọn.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 8