Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 7:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Olúwa wí fún Gídíónì pé, “Àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó lá omi ni èmi yóò lò láti gbà yín là àti láti fi ogun Mídíánì lé yín lọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn tókù padà sí ilé wọn.”

8. Báyìí ni Gídíónì ṣe dá àwọn Ísírẹ́lì tí ó kù padà sí àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó dá àwọn ọ̀ọ́dúrún ọkùnrin náà dúró. Àwọn wọ̀nyí sì gba gbogbo ohun èlò àti fèrè àwọn tí ó ti padà.Ibùdó ogun àwọn Mídíánì wà ní àfonífojì ní ìṣàlẹ̀. Ibi tí ó wà.

9. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa sọ fún Gídíónì pé, “Dìde, dojú ogun kọ ibùdó ogun àwọn ará Mídíánì nítorí èmi yóò fi lé ọ lọ́wọ́.

10. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀rù àti kọlù wọ́n bá ń bà ọ́, yọ́ wọ ibùdó wọn lọ kí o mú Púrà ìránṣẹ́ rẹ lọ́wọ́

11. kí o sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ibùdó náà. Lẹ́yìn èyí ọkàn rẹ̀ yóò le láti kọlù ibùdó náà.” Báyìí ni òun àti Púrà ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ẹnu ọ̀nà ibùdó yìí.

12. Àwọn ará Mídíánì, àwọn ará Ámẹ́lẹ́kì àti gbogbo ènìyàn ìlà oòrùn tó lọ ní àfonífojì bí esú ni wọ́n rí nítorí púpọ̀ wọn. Àwọn ràkúnmí wọn kò sì lóǹkà, wọ́n sì pọ̀ bí yanrìn inú òkun.

13. Gídíónì dé sí àsìkò tí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ àlá tí ó lá sí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní, “Mo lá àlá kan, nínú àlá náà mo rí àkàrà kan tó ṣe róbótó tí a fi Báálì ṣe ń yí wọ inú ibùdó àwọn ará Mídíánì, ó sì kọlu àgọ́ pẹ̀lú agbára ńlá débi wí pé àgọ́ náà dojú dé, ó sì ṣubú.”

14. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Èyí kò le túmọ̀ sí ohun mìíràn ju idà Gídíónì ọmọ Jóásì ará Ísírẹ́lì lọ: Ọlọ́run ti fi àwọn ará Mídíánì àti gbogbo ogun ibùdó lé e lọ́wọ́.”

15. Nígbà tí Gídíónì gbọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ sin Ọlọ́run: lẹ́yìn náà ni ó padà sí ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì pè wọ́n pé, “Ẹ dìde! Nítorí pé Ọlọ́run yóò lò yín láti ṣẹ́gun gbogbo ogun Mídíánì.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 7