Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 6:27-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Gídíónì mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe.

28. Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Báálì àti pé a ti bẹ́ igi òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rúbọ lóríi pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ.

29. Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?”Lẹ́yìn tí wọn fara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gídíónì ọmọ Jóásì ni ó ṣe é.”

30. Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Jóásì wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì lulẹ̀ ó sì ti ké òpó Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.”

31. Ṣùgbọ́n Jóásì bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Báálì bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Báálì bá ṣe Ọlọ́run ní tòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.”

32. Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gídíónì ní “Jérúbáálì” wí pé, “Jẹ́kí Báálì bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Báálì.

33. Láìpẹ́ jọjọ àwọn ogun àwọn Mídíánì, ti àwọn Ámálékì àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà oòrùn yóòkù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá Jọ́dánì wọ́n sì tẹ̀dó sí àfonífojì Jésírẹ́lì.

34. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Gídíónì, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Ábíésérì láti tẹ̀lé òun.

35. Ó rán àwọn oníṣẹ́ la ilẹ̀ Mánásè já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Ásérì, Ṣébúlúnì àti Náfítalì gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn.

36. Gídíónì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí ìwọ yóò bá gba Ísírẹ́lì là nípaṣẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí—

37. kíyèsí, èmi yóò fi awọ irun àgùntàn lé ilẹ̀ ìpakà ní alẹ́ òní. Bí ìrì bá ṣẹ̀ sí orí awọ yìí nìkan tí gbogbo ilẹ̀ yóòkù sì gbẹ, nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ lóòótọ́ pé ìwọ yóò gba Ísírẹ́lì là nípaṣẹ̀ mi bí ìwọ ti sọ.”

38. Èyí ni ó sì ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Gídíónì jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ó sì fún irun àgùntàn náà, páànù omi kan sì kún.

39. Gídíónì sì tún wí fún Olúwa pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú sí mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n tún wá ìdánilójú kan sí i, èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí n fi awọ irun yìí ṣe ìdánwò kan síi. Ní àsìkò yìí, jẹ́ kí awọ irun yìí gbẹ kí gbogbo ilẹ̀ sì tutù pẹ̀lú ìrì.”

40. Ní òru náà Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, awọ irun àgùntàn nìkan ni ó gbẹ; gbogbo ilẹ̀ yóòkù sì tutù nítorí ìrì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 6