Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 5:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “Ní àwọn ọjọ́ Ṣámgárì ọmọ Ánátì,Ní àwọn ọjọ́ Jáélì, a kọ àwọn ojú ọ̀nà sílẹ̀;àwọn arìnrìnàjò ń gba kọ̀rọ̀ kọ́rọ́.

7. Àwọn akọni ìletò dínkù,wọ́n dínkù afi ìgbà tí Dèbórà dìde,ó dìde bí ìyá ní Ísírẹ́lì.

8. Nígbà tí Ísírẹ́lì bá yan Ọlọ́run àjèjì,ogun jíjà wọ ibodè ìlúa kò rí àpáta tàbí ọ̀kọ̀láàárin àwọn ẹgbàá ní Ísírẹ́lì

9. Inú mi yọ̀ sí àwọn aláṣẹ Ísírẹ́lìàwọn tí ó fi tínu tínu fi ara wọn rúbọẸ yín Olúwa!

10. “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,ẹ̀yin tí ń jókòó láti se ìdájọ́,àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà,Ní ọ̀nà jìnjìn sí

11. ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.Wọ́n ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa níbẹ̀,àní iṣẹ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwasọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibodè.

12. ‘Jí, jí, Dèbórà!Jí, jí, kó orin dìde!Dìde Bárákì!Kó àwọn ìgbékùn rẹ ní ìgbékùn ìwọ ọmọ Ábínóámù.’

13. “Nígbà náà ni ó fi àwọn tókùjọba lórí àwọn ènìyàn; Olúwa fún mi ìjọbalórí àwọn alágbára.

14. Àwọn kan jáde wá láti Éfúráímù, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Ámélékì;Bẹ́ńjámínì wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.Láti Mákírì ni àwọn alásẹ ti sọ̀ kalẹ̀ wá,láti Ṣébúlúnì ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.

15. Àwọn ọmọ aládé Ísákárì wá pẹ̀lú Dèbórà;bẹ́è ni, Ísákàrì wà pẹ̀lú Bárákì,wọ́n fi ẹṣẹ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.Ní ipadò Rúbẹ́nìni ìgbèrò púpọ̀ wà.

16. Èéṣe tí ìwọ fi jókòó láàárin agbo àgùntànláti máa gbọ́ fèrè olùsọ́-àgùntàn?Ní ipadó Rúbẹ́nìni ìgbèrò púpọ̀ wà.

17. Gílíádì jókòó ní òkè odò Jọ́dánì.Èéṣe tí Dánì fi jókòó nínú ọkọ̀ ojú omi?Ásérì jòkòó ní etí bèbè òkun,ó sì n gbé èbúté rẹ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 5