Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 5:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. “Alábùkún jùlọ nínú àwọn ọmọ obìnrin ni Jáélì,aya Hébérì ará Kénì,alábùkún jùlọ nínú àwọn obìnrin tí ń gbé inú àgọ́.

25. Ó bèèrè omi, ó fún un ní wàrà;ó fi àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́la fún un ni wàrà dídì.

26. Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà.Ó kan Ṣísérà mọ́lẹ̀ pẹ̀lú òòlù ọwọ́ rẹ̀, ó fọ́ ọ ní orí,Ó kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ sinsiǹ.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 5