Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 5:10-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. “Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,ẹ̀yin tí ń jókòó láti se ìdájọ́,àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà,Ní ọ̀nà jìnjìn sí

11. ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.Wọ́n ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa níbẹ̀,àní iṣẹ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwasọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibodè.

12. ‘Jí, jí, Dèbórà!Jí, jí, kó orin dìde!Dìde Bárákì!Kó àwọn ìgbékùn rẹ ní ìgbékùn ìwọ ọmọ Ábínóámù.’

13. “Nígbà náà ni ó fi àwọn tókùjọba lórí àwọn ènìyàn; Olúwa fún mi ìjọbalórí àwọn alágbára.

14. Àwọn kan jáde wá láti Éfúráímù, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Ámélékì;Bẹ́ńjámínì wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.Láti Mákírì ni àwọn alásẹ ti sọ̀ kalẹ̀ wá,láti Ṣébúlúnì ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.

15. Àwọn ọmọ aládé Ísákárì wá pẹ̀lú Dèbórà;bẹ́è ni, Ísákàrì wà pẹ̀lú Bárákì,wọ́n fi ẹṣẹ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.Ní ipadò Rúbẹ́nìni ìgbèrò púpọ̀ wà.

16. Èéṣe tí ìwọ fi jókòó láàárin agbo àgùntànláti máa gbọ́ fèrè olùsọ́-àgùntàn?Ní ipadó Rúbẹ́nìni ìgbèrò púpọ̀ wà.

17. Gílíádì jókòó ní òkè odò Jọ́dánì.Èéṣe tí Dánì fi jókòó nínú ọkọ̀ ojú omi?Ásérì jòkòó ní etí bèbè òkun,ó sì n gbé èbúté rẹ̀.

18. Àwọn ènìyàn Ṣébúlúnì fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú;bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Náfítalì ní ibi gíga pápá.

19. “Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;àwọn ọba Kénánì jàní Tánákì ní etí odo Mégídò,ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.

20. Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wáláti ibùjókòó wọn ni wọ́n ti bá Ṣísérà jà.

21. Odò Kísónì agbá wọn lọ,odò àtijọ́ náà, odò Kíṣónì.Má a yan lọ ìwọ ọkàn mi, jẹ́ alágbára pẹ̀lú!

22. Nígbà náà ni pátakò ẹṣẹ̀ ẹsin ki ilẹ̀,nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn.

23. ‘Ẹ fi Mérósì,’ bú ni ańgẹ́lì Olúwa wí.‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ gégùn ún kíkorò,nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ OLÚWÁ,láti dojúkọ àwọn alágbára.’

24. “Alábùkún jùlọ nínú àwọn ọmọ obìnrin ni Jáélì,aya Hébérì ará Kénì,alábùkún jùlọ nínú àwọn obìnrin tí ń gbé inú àgọ́.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 5