Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 3:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé láàárin àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì àwọn ará Ámórì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífítì àti àwọn ará Jébúsì.

6. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Ísírẹ́lì ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.

7. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa. Wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Báálímù àti Áṣérótù.

8. Ìbínú Olúwa sì ru sí Ísírẹ́lì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kúṣánì Rísíkítaímù ọba Árámù-Náháráímù (ìlà oòrùn Síríà) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.

9. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Ótíníẹ́lì ọmọ Kénánì àbúrò Kálẹ́bù tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.

10. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, ó sì di onídàájọ́ (aṣíwájú) Ísírẹ́lì ó sì ṣíwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kúṣánì-Ríṣátaímù lé Ótíníẹ́lì lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

11. Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Ótíníẹ́lì fi kú.

12. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú Olúwa, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí. Olúwa fún Égílónì, ọba àwọn Móábù ní agbára ní orí Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 3