Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran túntún ní Ísírẹ́lì wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun, àwọn ará Kénánì.

2. (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Ísírẹ́lì tí kò rí ogun rí ní bí a ti ṣe ń jagun):

3. Àwọn ìjòyè ìlú Fílístínì máràrùn, gbogbo àwọn ará Kénánì, àwọn ará Ṣídónì, àti àwọn ará Hífì tí ń gbé ní àwọn òkè Lébálónì bẹ̀rẹ̀ láti òkè Báálì-Aámónì títí dé Lébò Hámátì.

4. A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Ísírẹ́lì wò bóyá wọn yóò gbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipaṣẹ̀ Móṣè.

5. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé láàárin àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì àwọn ará Ámórì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífítì àti àwọn ará Jébúsì.

6. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Ísírẹ́lì ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.

7. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa. Wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Báálímù àti Áṣérótù.

8. Ìbínú Olúwa sì ru sí Ísírẹ́lì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kúṣánì Rísíkítaímù ọba Árámù-Náháráímù (ìlà oòrùn Síríà) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.

9. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Ótíníẹ́lì ọmọ Kénánì àbúrò Kálẹ́bù tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.

10. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, ó sì di onídàájọ́ (aṣíwájú) Ísírẹ́lì ó sì ṣíwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kúṣánì-Ríṣátaímù lé Ótíníẹ́lì lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 3