Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 21:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àwọn ènìyàn náà mọ pẹpẹ kan wọ́n sì rúbọ ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìrẹ́pọ̀ (ìbáṣepọ̀, àlàáfíà).

5. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì béèrè wí pé, “Èwo nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ó kọ̀ láti péjọ ṣíwájú Olúwa?” Torí pé wọ́n ti fi ìbúra ńlá búra pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti péjọ níwájú Olúwa ní Mísípà pípa ni àwọn yóò pa á.

6. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì banújẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Wọ́n wí pé, “A ti ké ẹ̀yà kan kúrò lára Ísírẹ́lì lónìí.”

7. Báwo ni a ó ò ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù, nítorí àwa ti fi Olúwa búra láti má fi ọ̀kankan nínú àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya.

8. Wọ́n sì béèrè wí pé, “È wo ni nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ó kọ̀ láti bá àwọn ènìyàn péjọ níwájú Olúwa ní Mísípà?” Wọ́n ríì pé kò sí ẹnìkankan tí ó wa láti Jabesi-Gílíádì tí ó wá sí ibùdó fún àjọ náà.

9. Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkan kan láti inú àwọn ará Jabesi-Gílíádì tí ó wà níbẹ̀.

10. Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gílíádì wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 21