Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 20:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gíbíà lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú.

6. Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí-ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbégbé ìní Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

7. Nísinsinyìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.”

8. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnìkankan nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò se sí Gíbíà ní yìí: Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa.

10. A ó ò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn ún nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì àti ọgọ́rùn ún (100) láti inú ẹgbẹ̀rún (1000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.”

11. Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì para pọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.

12. Àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárin yín?

13. Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gíbíà yìí wá fún wa, kí àwa lé pa kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Ísírẹ́lì.”Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 20