Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 20:35-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Olúwa ṣẹ́gun Bẹ́ńjámínì níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ẹgbàá méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,000) ọkùnrin Bẹ́ńjámínì, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun.

36. Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn.Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì fà sẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gíbíà.

37. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gíbíà, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà.

38. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti àwọn tí ó lúgọ sínú igbó ti fún ara wọn ní àmì pé, kí àwọn tí ó lúgọ fi ẹ̀ẹ́fín ṣe ìkúukùú ńlá láti inú ìlú náà,

39. nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yípadà, wọ́n sá gun.Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó to ọgbọ̀n (30), wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.”

40. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkúukùú ẹ̀ẹ́fín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì yípadà wọ́n sì rí ẹ̀ẹ́fín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run.

41. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu.

42. Wọ́n sì sá níwáju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀.

43. Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbégbé ìlà oòrùn Gíbíà.

44. Ẹgbàá mẹ́sàn án (18,000) àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun.

45. Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sá lọ sí apá aṣálẹ̀ lọ sí ọ̀nà àpáta Rímónì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì títí dé Gídómù wọ́n sì tún bi ẹgbàá (2000) ọkùnrin ṣubú.

46. Ní ọjọ́ náà ẹgbàá méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Bẹ́ńjámínì tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun.

47. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rámónù, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin.

48. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì padà sí àwọn ìlú Bẹ́ńjámínì wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 20