Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 2:13-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nítorí tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Báálì àti Ásítarótù.

14. Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀ta wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí.

15. Nígbà-kí-ìgbà tí àwọn Ísírẹ́lì bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀ta a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn, wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.

16. Olúwa gbé àwọn onídájọ́ (aṣíwájú tí ó ní agbára) dìde sí àwọn tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn.

17. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbérè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọràn sí àwọn òfin Olúwa.

18. Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀ta wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láàyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n.

19. Ṣùgbọ́n ní gbàrà tí onídàájọ́ bá ti kú àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn.

20. Ìbínú Olúwa yóò sì tún ru sí Ísírẹ́lì a sì wí pé, “Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mu tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi.

21. Èmi kì yóò lé ọ̀kankan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Jóṣúà fi sílẹ̀ nígbà tí ó kú jáde.

22. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ èmi yóò lo àwọn orílẹ̀-èdè yìí láti fi dán Ísírẹ́lì wò, láti mọ̀ bóyá wọ́n yóò pa ọ̀nà Olúwa mọ́ àti pé bóyá wọn ó rìn nínú rẹ̀ bí àwọn baba ńlá wọn ti rìn.”

23. Nítorí náà Olúwa fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì pa wọ́n run.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 2