Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 19:26-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Nígbà tí ojúmọ́ bẹ̀rẹ̀ sí là obìnrin náà padà lọ sí ilé tí ọ̀gá rẹ̀ wà, ó ṣubú lulẹ̀ lọ́nà, ó sì wà níbẹ̀ títí ó fi di òwúrọ̀.

27. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ jí tí ó sì dìde ní òwúrọ̀ tí ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé náà, tí ó sì bọ́ sí òde láti tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, kíyèsí i àlè rẹ̀ wà ní síṣubú ní iwájú ilé, tí ọwọ́ rẹ̀ sì di òpó ẹnu ọ̀nà ibẹ̀ mú,

28. òun sì wí fún obìnrin náà pé, “Dìde jẹ́ kí a máa bá ọ̀nà wa lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò dá a lóhùn. Nígbà náà ni ọkùnrin náà gbé e lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì kọjá lọ sí ilé e rẹ̀.

29. Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ ó sì gé àlè rẹ̀ ní oríkeríke sí ọ̀nà méjìlá, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì.

30. Gbogbo ẹni tí ó rí i sì wí pé, “A kò ti rí i, bẹ́ẹ̀ a kò tí ì ṣe irú nǹkan yìí rí, kì í ṣe láti ọjọ́ tí Ísírẹ́lì ti jáde tí Éjíbítì wá títí di òní olónìí. Ẹrò ó wò, ẹ gbìmọ̀ràn kí ẹ sọ fún wa ohun tí a ó ò ṣe!”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 19