Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 19:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Ísírẹ́lì kò ní ọba.Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Léfì tí ń gbé ibi tí ó sápamọ́ nínú àwọn agbégbé òkè Éfúráímù, mú àlè kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà.

2. Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà jẹ́ aláìṣòótọ́ sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti lo oṣù mẹ́rin ní ilé baba rẹ̀

3. ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀ tayọ̀ gbà á.

4. Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀.

5. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.”

6. Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó wọn láti jọ jẹun àti láti jọ mu. Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ.”

7. Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, baba ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́, torí náà ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà.

8. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, “Fi oúnjẹ gbé ara ró. Dúró de ọ̀sán!” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 19