Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 18:20-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú èfódì náà, àwọn òrìsà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ.

21. Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn ṣíwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ.

22. Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Míkà, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbégbé Míkà kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dánì bá.

23. Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dánì yípadà wọ́n sì bi Míkà pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?”

24. Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ”

25. Àwọn ọkùnrin Dánì náà dáhùn pé, “Má se bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.”

26. Àwọn ọkùnrin Dánì náà sì bá ọ̀nà wọn lọ. Nígbà tí Míkà rí í pé wọ́n lágbára púpọ̀ fún òun, ó sì padà sí ilé rẹ̀.

27. Wọ́n sì kó àwọn ohun tí Míkà ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí Láísì, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run.

28. Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará Ṣídónì, wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bá a Bẹti-Réhóbù.Àwọn ará Dánì sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀.

29. Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní Dánì gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn Dánì, ẹni tí wọ́n bí fún Ísírẹ́lì: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Láísì ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí.

30. Àwọn ọmọ Dánì sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀; Jónátanì ọmọ Gáṣómì, ọmọ Móṣè, àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà Dánì títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbékùn.

31. Wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti lo àwọn ère tí Míkà ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣílò.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 18