Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 16:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Àwọn ará Gásà sì gbọ́ wí pé, “Sámúsónì wà níbí.” Wọ́n sì yí agbégbé náà ká, wọ́n ń ṣọ́ ọ ní gbogbo òru náà ní ẹnu bodè ìlú náà. Wọn kò mira ní gbogbo òrú náà pé ní “àfẹ̀mọ́júmọ́ àwa yóò pa á”

3. Ṣùgbọ́n Sámúsónì sùn níbẹ̀ di àárin ọ̀gànjọ́ (èyí nì di agogo méjìlá òru). Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀. Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hébírónì.

4. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó sì ní ìfẹ́ obìnrin kan ní àfonífojì Ṣórékì, orúkọ ẹni tí í ṣe Dẹ̀lílà.

5. Àwọn ìjòyè Fílístínì sì lọ bá obìnrin náà, wọ́n sọ fún un wí pé, “Bí ìwọ bá le tàn án kí òun sì fi àsírí agbára rẹ̀ hàn ọ́, àti bí àwa ó ti lè borí rẹ̀, kí àwa sì dè é kí àwa sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wa yóò sì fún ọ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà fàdákà.”

6. Torí náà Dẹ̀lílà sọ fún Sámúsónì pé, “Sọ àsírí agbára ńlá rẹ fún mi àti bí wọ́n ti le dè ọ́, àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ.”

7. Sámúsónì dá a lóhùn wí pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fi okùn tútù méje tí ẹnìkan kò sá gbẹ dè mí, èmi yóò di aláìlágbára bí i gbogbo àwọn ọkùnrin yóòkù.”

8. Àwọn olóyè Fílístínì sì mú okùn tútù méje tí ẹnikẹ́ni kò sá gbẹ wá fún Dẹ̀lílà òun sì fi wọ́n dè é.

9. Nígbà tí àwọn ènìyàn tí sá pamọ́ sínú yàrá, òun pè pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì ti dé láti mú ọ.” Ṣùgbọ́n òun já àwọn okùn náà bí òwú ti í já nígbà tí ó bá wà lẹ́bàá iná. Torí náà wọn kò mọ àsírí agbára rẹ̀.

10. Dẹ̀lílà sì sọ fún Sámúsónì pé, ìwọ ti tàn mí; o sì purọ́ fún mi. Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́.

11. Òun dáhùn pé, “Bí wọ́n bá lè fi okùn túntún tí ẹnikẹ́ni kò tíì lò rí dì mí dáadáa, èmi yóò di aláìlágbára, èmì yóò sì dàbí àwọn ọkùnrin yóòkù.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 16