Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 12:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Lẹ́yìn rẹ̀, Élónì ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì ṣe àkóso Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá.

12. Élónì sì kú, wọ́n sì sin ín sí Áíjálónì ní ilẹ̀ Ṣébúlúnì.

13. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ábídónì ọmọ Hiélì tí Pírátónì n ṣe àkóso Ísírẹ́lì.

14. Òun ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ ọmọ àwọn tí ó ń gun àádọ́rin (70) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́jọ.

15. Ábídónì ọmọ Híélì sì kú, wọ́n sin ín sí Pírátónì ní ilé Éfúráímù ní ìlú òkè àwọn ará Ámálékì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 12