Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 1:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ọba Adoni-Bésékì sá àṣálà, ṣùgbọ́n ogun Ísírẹ́lì lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀.

7. Nígbà náà ni ó wí pé, àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń sa ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Olúwa ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn, wọ́n sì mú un wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kú sí bẹ̀.

8. Àwọn ológun Júdà sì ṣẹ́gun Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.

9. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní Gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀ oòrùn Júdà jagun.

10. Ogun Júdà sì tún sígun tọ ará Kénánì tí ń gbé Hébírónì (tí ọrúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíríátì-Arábà) ó sì sẹ́gun Ṣẹ́ṣáì-Áhímánì àti Táímà.

11. Lẹ́yìn èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn tí ń gbé Débírì jagun (orúkọ Débírì ní ìgbà àtijọ́ ni Kíríátì-Ṣéférì tàbí ìlú àwọn ọ̀mọ̀wé).

12. Kélẹ́bù sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́ ṣíwájú ogun tí Kíríátì-Ṣáférì tí ó sì Ṣẹ́gun rẹ̀ ni èmi ó fún ní ọmọbìnrin mi Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.”

13. Ótíníẹ́lì ọmọ Kénásì àbúrò Kélẹ́bù ṣíwájú, wọ́n sì kọ lu ìlú náà, ó sì fún un ní Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.

14. Ní ọjọ́ kan nígbà tí Ákíṣà wá sí ọ̀dọ̀ Ótíníélì, ó rọ ọkọ rẹ̀ láti tọrọ oko lọ́wọ́ Kélẹ́bù baba rẹ̀. Nígbà tí Ákíṣà ti sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ Kélẹ́bù bi í léèrè pé, “Kí ni o ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ.”

15. Ákíṣà sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojú rere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Gúúsù (gúṣù) fún mi ní ìṣun omi náà pẹ̀lú.” Kélẹ́bù sì fún un ní ìṣun òkè àti ìṣun ìṣàlẹ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 1