Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 1:4-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Júdà sì kọ lu àwọn ọmọ Kénánì, Olúwa ran àwọn Júdà lọ́wọ́, ó sì fi àwọn ará Kénánì àti àwọn ará Párísì lé wọn lọ́wọ́, àwọn Júdà sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Béṣékì nínú àwọn ọ̀ta wọn.

5. Ní Béṣékì ni wọ́n ti rí Adoni-Bésékì (Olúwa mi ní Béṣékì), wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kénánì àti Párísì.

6. Ọba Adoni-Bésékì sá àṣálà, ṣùgbọ́n ogun Ísírẹ́lì lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀.

7. Nígbà náà ni ó wí pé, àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń sa ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Olúwa ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn, wọ́n sì mú un wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kú sí bẹ̀.

8. Àwọn ológun Júdà sì ṣẹ́gun Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.

9. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní Gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀ oòrùn Júdà jagun.

10. Ogun Júdà sì tún sígun tọ ará Kénánì tí ń gbé Hébírónì (tí ọrúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kíríátì-Arábà) ó sì sẹ́gun Ṣẹ́ṣáì-Áhímánì àti Táímà.

11. Lẹ́yìn èyí wọ́n tẹ̀ṣíwájú láti bá àwọn tí ń gbé Débírì jagun (orúkọ Débírì ní ìgbà àtijọ́ ni Kíríátì-Ṣéférì tàbí ìlú àwọn ọ̀mọ̀wé).

12. Kélẹ́bù sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́ ṣíwájú ogun tí Kíríátì-Ṣáférì tí ó sì Ṣẹ́gun rẹ̀ ni èmi ó fún ní ọmọbìnrin mi Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.”

13. Ótíníẹ́lì ọmọ Kénásì àbúrò Kélẹ́bù ṣíwájú, wọ́n sì kọ lu ìlú náà, ó sì fún un ní Ákíṣà gẹ́gẹ́ bí aya.

14. Ní ọjọ́ kan nígbà tí Ákíṣà wá sí ọ̀dọ̀ Ótíníélì, ó rọ ọkọ rẹ̀ láti tọrọ oko lọ́wọ́ Kélẹ́bù baba rẹ̀. Nígbà tí Ákíṣà ti sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ Kélẹ́bù bi í léèrè pé, “Kí ni o ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 1