Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 9:16-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe títí, ìkúùkù yóò bò ó lọ́sán, ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná lálẹ́.

17. Nígbàkígbà tí ìkúùkù yìí bá ká sókè kúrò lórí àgọ́ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dìde láti máa lọ; ibikíbi tí ìkúùkù náà bá dúró sí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò pa ibùdó wọn sí.

18. Nípa àṣẹ Olúwa ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jáde lọ, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkúùkù bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó.

19. Nígbà tí ìkúùkù bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa wọn kò sì ní gbéra láti lọ.

20. Ìgbà mìíràn ìkúùkù lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; ṣíbẹ̀ ní àṣẹ Olúwa, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra.

21. Ìgbà mìíràn ìkúùkù lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá sì kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkigbà tí ìkúùkù bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra.

22. Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkúùkù fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn ò ní í gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra.

23. Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 9