Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 8:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Olúwa sọ fún Mósè pé,

24. “Èyí ni ohun tó jẹ mọ́ àwọn ọmọ Léfì: Láti ọmọ ọdún kẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni kí ó máa kópa nínú iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé.

25. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá ti pé ọmọ àádọ́ta ọdún gbọdọ̀ síwọ́ nínú iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn nínú àgọ́, kí wọ́n sì má ṣiṣẹ́ mọ́

26. Wọ́n le máa ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Báyìí ni kí o ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Léfì.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 8