Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 7:49-69 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ

50. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí

51. akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun

52. akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

53. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Élísámà ọmọ Ámíhúdì.

54. Gàmálíèlì ọmọ Pédáṣúrì, olórí àwọn ọmọ Mánásè ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹjọ.

55. Ọrẹ tirẹ̀ ni, àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

56. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

57. akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

58. akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

59. màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Gámálíélì ọmọ Pédásúrì.

60. Ábídánì ọmọ Gídíónì, olórí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹsan-an.

61. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

62. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

63. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

64. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

65. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ábídánì ọmọ Gídíónì.

66. Áhíésérì ọmọ Ámíṣádáyì, olórí àwọn ọmọ Dánì ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹwàá.

67. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo sílifà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

68. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

69. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 7