Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 7:40-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

41. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Sélúmíélì ọmọ Surisádáì.

42. Eliásáfì ọmọ Déúélì olórí àwọn ọmọ Gáádì ní ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹfà.

43. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí iwọn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò bí ẹbọ ohun jíjẹ

44. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí

45. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun

46. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀

47. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliásáfì ọmọ Déúélì.

48. Élísámà ọmọ Ámíhúdì, olórí àwọn ọmọ Éfúráímù ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ keje.

49. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ

50. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 7