Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 7:32-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

33. Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;

34. Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

35. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Élísúrì ọmọ Ṣédéúrì.

36. Ṣélúmíélì ọmọ Suriṣádáì, olórí àwọn ọmọ Símónì ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún.

37. Ọrẹ tí ó kó wá ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ́;

38. Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 7