Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 7:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Móṣè ti pári gbígbé àgọ́ dúró, ó ta òróró sí i, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, Ó tún ta òróró sí pẹpẹ, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀.

2. Nígbà náà ni àwọn olórí Ísírẹ́lì, àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn alábojútó àwọn tí a kà náà mú ọrẹ wá.

3. Wọ́n mú ọrẹ wọn wá ṣíwájú Olúwa: kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà ti abo, àti akọ màlúù kan láti ọ̀dọ̀ olórí kọ̀ọ̀kan àti kẹ̀kẹ́ ẹrù kan láti ọ̀dọ̀ olórí méjì. Wọ́n sì kó wọn wá sí iwájú àgọ́.

4. Olúwa sọ fún Mósè pé:

5. “Gba gbogbo nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n ba à lè wúlò fún iṣẹ́ inú Àgọ́ Ìpàdé. Kó wọn fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe nílò rẹ̀.”

6. Mósè sì kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti akọ màlúù náà fún àwọn ọmọ Léfì.

7. Ó fún àwọn ọmọ Gáṣónì ní kẹ̀kẹ́ méjì àti akọ màlúù mẹ́rin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́.

8. O fún àwọn ọmọ Mérárì ní kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti akọ màlúù mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Gbogbo wọn wà lábẹ́ àkóso Ítamárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà.

9. Ṣùgbọ́n Mósè kò fún àwọn ọmọ Kóhátì ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn.

10. Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ. Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá ṣíwájú pẹpẹ.

11. Nítorí tí Olúwa ti sọ fún Mósè pé, “Olórí kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa mú ọrẹ tirẹ̀ wá ṣíwájú pẹpẹ.”

12. Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ni Náṣónì ọmọ Ámínádábù láti inú ẹ̀yà Júdà.

13. Ọrẹ rẹ̀ jẹ́ àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 7