Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé:

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.

3. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má báà ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrin wọn”

4. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mósè.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 5