Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 35:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé,

10. “Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jọ́dánì sí Kénánì,

11. Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sá lọ síbẹ̀.

12. Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹní tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má baà kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́.

13. Mẹ́fà nínú ìlú tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín.

14. Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jọ́dánì, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kénánì tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí.

15. Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, fún àlejò àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrin wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sá lọ ṣíbẹ̀.

16. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pá, apànìyàn náà.

17. Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà.

18. Tàbí tí ènìyàn bá mú ohun èlò igi ní ọwọ́ ọ rẹ̀ tí ó sì lẹ̀ ẹ́ pa ènìyàn, tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni; pípa ní a ó pa apànìyàn náà.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 35