Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 35:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní Jọ́dánì tí ó rékọjá láti Jẹ́ríkò, Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fún àwọn Léfì ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú.

3. Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.

4. “Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Léfì, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ (1500) ẹsẹ̀ bàtà láti ògiri ìlú náà.

5. Lẹ́yin náà, wọn ẹgbẹ̀ẹ́dogun (3000) ẹṣẹ̀ bàtà lápá ibi ìhà ìlà oòrùn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ẹṣẹ̀ bàtà ní ìhà gúsù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àríwá. Pẹ̀lú ìlú ní àárin. Wọn yóò ní agbégbé yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.

6. “Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ ìlú ibi ìsásí, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì (42) ìlú sí i.

7. Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì ní éjìdínláàdọ́ta (48) ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.

8. Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”

9. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé,

10. “Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jọ́dánì sí Kénánì,

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 35