Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 33:31-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Wọ́n kúrò ní Mósérótù wọ́n sì pàgọ́ ní Bene-Jákánì.

32. Wọ́n kúrò ní Bene-Jákánì wọ́n sì pàgọ́ ní Hori-Hágidigádì.

33. Wọ́n kúrò ní Hori-Hágidigádì wọ́n sí pàgọ́ ní Jótíbátà.

34. Wọ́n kúrò ní Jótíbátà wọ́n sì pàgọ́ ní Ábírónà.

35. Wọ́n kúrò ní Ábírónà wọ́n sì pàgọ́ ní Esoni-Gébérì.

36. Wọ́n kúrò ní Esoni-Gébérì wọ́n sì pàgọ́ ní Kádésì nínú ihà Ṣínì.

37. Wọ́n kúrò ní Kádésì wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hórì, lẹ́bá Édómù.

38. Nípa àsẹ Olúwa, Árónì àlùfáà gùn orí òkè Hórì, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kárun, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ilẹ̀ Éjíbítì jáde wá.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 33