Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 32:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ẹ kọ́ ilé fún àwọn obìnrin yín àti ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àti ilé fún agbo ẹran yín, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó ṣe ohun tí ẹ ti pinnu.”

25. Àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì sọ fún Mósè pé, “Àwa ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa wa ti paláṣẹ.

26. Àwọn ọmọ wa àti ìyàwó wa, àwọn agbo ẹran àti ohun ọ̀sìn wa yóò dúró ní ìlú Gílíádì.

27. Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra ogun, yóò ré kọjá lọ láti jà níwájú Olúwa; gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti sọ.”

28. Nígbà náà ni Mósè pàṣẹ nípa wọn fún Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọ Núnì àti sí gbogbo olórí ìdílé ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

29. Ó wí fún wọn pé, “Tí àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra fún ogun rékọjá odò Jọ́dánì pẹ̀lú níwájú Olúwa, nígbà tí ẹ ṣegun ilẹ̀ náà níwájú yín, Fún wọn ní ilẹ̀ Gílíádì gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

30. Ṣùgbọ́n tí wọn kò bá fẹ́ bá yín rékọjá pẹ̀lú ìhámọ́ra, wọn gbọdọ̀ gba ìní wọn pẹ̀lú yín ní Kénánì.”

31. Àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì dáhùn pé, “Iránṣẹ́ rẹ yóò ṣe ohun tí Olúwa ti sọ.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 32