Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 32:12-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. kò sí ẹnìkankan àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì àti Jóṣúà ọmọ Núnì, nítorí wọ́n tẹ̀lé Olúwa tọkàntọkàn.’

13. Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì mú wọn rìn ní ihà fún ogójì (40) ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ.

14. “Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò bàbá yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná Olúwa ru sí Ísírẹ́lì.

15. Tí ẹ̀yin bá yípadà ní ẹ̀yìn rẹ̀ yóò sì fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ ní ihà, ìwọ yóò sì mú-un ṣe ìparun.”

16. Nígbà náà wọ́n wá sí òkè ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, “Àwa yóò fẹ́ láti kọ́ ilé ẹran níhínyìí fún ohun ọ̀sìn wa, àti ìlú fún àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa.

17. Ṣùgbọ́n àwa ṣetán láti dira ogun ṣááju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí tí a yóò fi mú wọn dé ọ̀dọ̀ wọn lákokò yìí, àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa yóò gbé inú ìlú tí a mọ odi sí fún ìdábòbò wọn lọ́wọ́ olùgbé ilẹ̀ náà.

18. A kì yóò padà sí ilẹ̀ wa láì ṣe pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gba ogún wọn.

19. A kì yóò gba ogún kankan pẹ̀lú wọn ní òdìkejì Jọ́dánì, nítorí ogún ti wa, ti wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì.”

20. Nígbà náà ni Mósè sọ fún wọn pé, “Tí ẹ̀yin yóò bá pa ara yín lára, níwájú Olúwa fún ogún.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 32