Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 32:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn àti ohun ọ̀sìn rí wí pé ilé Jásérì àti Gádì dára fún ohun ọ̀sìn.

2. Nígbà náà wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà àti sí olórí gbogbo ìlú, wọ́n sì wí pé,

3. “Átarótì, Díbónì, Jásérì, Nímírà, Hésíbónì, Élíálì, Sébámù, Nébò, àti Béónì.

4. Ni ilẹ̀ tí Olúwa ti ṣẹ́gun níwájú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó sì dára fún ohun ọ̀sìn, ṣáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ohun ọ̀sìn.

5. Tí a bá rí ojú rere rẹ,” wọ́n wí, “jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní. Má se jẹ́kí a rékọjá odò Jọ́dánì.”

6. Mósè sọ fún àwọn ọmọ Gádì àti fún ọmọ Rúbẹ́nì pé, “Ṣé kí àwọn arákùnrin yín lọ sí ogun, kí ẹ̀yin kí ó sì jókó sí bí?

7. Kí ni ó dé tí o fi mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lọ sí ibi ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn?

8. Èyí ni nǹkan tí baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadesi-Báníyà láti lọ wo ilẹ̀ náà.

9. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ sí Àfonífojì Ésíkólù tí wọ́n rí ilẹ̀ náà, wọ́n mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn.

10. Ìbínú Olúwa sì dìde sí wọn ní ọjọ́ náà, ó sì búra, wí pé:

11. ‘Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Éjíbítì ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Ábúráhámù, fún Ísáákì àti fún Jákọ́bù:

12. kò sí ẹnìkankan àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì àti Jóṣúà ọmọ Núnì, nítorí wọ́n tẹ̀lé Olúwa tọkàntọkàn.’

13. Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì mú wọn rìn ní ihà fún ogójì (40) ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ.

14. “Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò bàbá yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná Olúwa ru sí Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 32