Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 31:19-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje, Ní ọjọ́ kẹ́ta àti ọjọ́ kéje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́.

20. Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe.”

21. Élíásárì àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mósè.

22. Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, tanńganran àti òjé.

23. Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ ó ò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.

24. Ní ọjọ́ kéje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”

25. Olúwa sọ fún Mósè pé,

26. “Ìwọ àti Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbékùn.

27. Pín ohun ìní àti ìkógún náà láàrin àwọn ọmọ ogun náà tí ó kópa nínú ogun náà àti láàrin gbogbo ìjọ.

28. Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà: ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ènìnyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran.

29. Gbà ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín ti wọn, kí o sì fún Élíásárì àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè Olúwa.

30. Lára ààbọ̀ ti Ísírẹ́lì, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, (50) yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Léfì, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.”

31. Nígbà náà Mósè àti Élíásárì àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè.

32. Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (675,000) ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àgùntàn.

33. Ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì (72,000) màlúù

34. ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

35. Pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógún, (32,000) ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.

36. Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́:ẹgbàá méjìdínláàdọ́san (337,500) ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ àgùntàn.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 31